Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Tope Alabi lóun yóò gba kóòtù lọ? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi (@tope_alabi_) /FB
Wẹrẹ ni iwe ikilọ naa jade sori ayelujara lopin ọsẹ, ti gbajumọ olorin ẹmi, Ajinyinrere Tope Alabi ti n sọ pe oun yoo gba kootu lọ.
Ohun ti Tope Alabi n sọ ni pe oun yoo gbe ẹni to ba gbe iroyin irọ nipa oun lọ sile ẹjọ, abi ti ibanilorukọjẹ.
O ni ẹni to ba si ba si ba wọn pin iroyin irọ naa paapaa yoo jẹgba ofin.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni Tope Alabi fi atẹjade sita, atẹjade lasan kọ, eyi to ti ileeṣẹ ofin kan, Oakmount Legal Practitioners, wa ni.
Ninu atẹjade naa ti Tope Alabi fi soju opo Instgram ati Facebook rẹ ni wọn ti ṣapejuwe rẹ bii olorin ẹmi, akọrin nile ati loke okun tawọn eeyan bọwọ fun.
Atẹjade naa sọ pe o ti fẹrẹ to ọgbọn odun bayii ti Tope Alabi ti n ṣiṣẹ tọ orukọ rere, to si n da aabo bo orukọ rẹ labẹ ofin.
Awọn amofin ti Tope Alabi fiṣẹ ran sọ pe:
"Onibaara wa ti gbọ pe iroyin irọ, aṣinilọna ati eyi to le ba orukọ rẹ jẹ to gba igboro kan, to si ṣee ṣe ki wọn tun maa pin in kiri yala ninu iwe iroyin, amohunmaworan, ori ayelujara tabi nipasẹ ọrọ ẹnu.
"Ẹnikẹni to ba gbe iroyin irọ jade nipa onibaara wa, yala nipasẹ kikọ, iwe iroyin, aworan, ori ayelujara, ifọrọwanilẹnuwo, ọrọ ẹnu ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo koju ofin fun ohun to gbe jade naa."

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi (@tope_alabi_) /FB

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi (@tope_alabi_) /FB
Ni afikun, wọn ni ẹsun naa le kan awọn ti wọn ba ran ẹni to gbe iroyin irọ naa jade lọwọ lati pin in kiri .
Ileeṣẹ ofin naa sọ pe ilana ti ẹni to ṣe ajọpin iroyin naa ba lo ni yoo sọ ibi ti ijiya tiẹ naa yoo de duro.
Ikilọ naa tẹsiwaju, pe kawọn ti wọn n lo oju opo ti ko lorukọ lori ayelujara ma ṣe ro pe wọn moribọ.
Wọn ni bi wọn ba gbe ohun ti ko ri bẹẹ nipa Tope Alabi, olorin ẹmi naa yoo fi ofin ba wọn ja.
"Ki ẹnikẹni to ba ti gbe iroyin naa jade tete gbe e kuro"

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi (@tope_alabi_) /FB
Ikede ati ikilọ naa sọ pe kawọn to ba ti gbe iroyin ofege ati ibanilorukọjẹ nipa Tope Alabi jade tete gbe e kuro nibi yowu ti won ba ti gbe e jade.
Wọn ni ki won ma si ṣe gbe iru rẹ mọ laye.
Awọn amofin ti olorin ẹmi naa gbesẹ fun sọ pe awọn ti gba aṣẹ lati fofin ba ẹni to ba tako ikilọ yii ja, lai si ikilọ kankan fun un mọ.
Wọn ni ki I ṣe pe Alabi n pa ohun mọ awọn eeyan lẹnu pẹlu ikede yii, awọn ko si di ẹtọ ọmọniyan lọwọ lati sọrọ ti ko mu wahala dani .
Awuyewuye wo lo bi igbesẹ yii?
Bo tilẹ jẹ pe awọn Amofin ti Tope gba ko ṣalaye idi kan pato to bi ikilọ yii, ikilọ naa jade bi awọn ọrọ kan ṣe n lọ lori ayelujara nia Tope Alabi.
Iroyin kan sọ pe ọrọ kan ti Tope sọ nipa ẹsin ibilẹ lo bi ikilọ yii, eyi ti awọn kan n yipada lodi si ohun ti Tope sọ .
Bakan naa ni fidio kan wa lori ayelujara, nibi ti ọkunrin kan ti n sọrọ nipa Tope Alabi ati Oloogbe Elijah Ajanaku ti Tope maa n fi kọrin nigba kan.
Fidio naa sọ pe Tope Alabi maa n fi orin yin Ajanaku nitori awọn idi kan, ti yoo tun maa darukọ rẹ mọ Ọlọrun, ti yoo maa sọ pe lagbara Ọlọrun Ajanaku.
Ọkunrin to n sọrọ ninu fidio naa tun sọ pe Tope Alabi ti ri mẹwaa ninu aye.
O ni ki wọn ba oun kalọ loju opo toun yoo ti tu winrinwinri ọrọ kalẹ.
Fidio yii ni awon eeyan tun n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ idi ti Tope Alabi fi n kilọ ree, ki wọn ma baa ba orukọ rẹ jẹ kaakiri aye.
Ta ló fẹ̀sùn kan Tope Alabi?

Oríṣun àwòrán, Pastor Tayo Ministries/Facebook
Obinrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Pastor Tayo Ministries lori ayelujara lo fi ẹsun kan Tope Alabi, Woli Arole, Dele Omo Wolii ati awọn miran pe wọn mọ nipa iku Toluwanisings.
Obinrin naa to fi orileede Canada ṣe ibugbe sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree toun yoo maa pe awọn eletutu jade lori ayelujara oun.
"Tope Alabi kii ṣe eletutu akọkọ ti ma maa pe jade. Ti Tope Alabi, Woli Arole ati gbogbo awọn to n pe ara wọn ni wolii, ati Dele Omo Woli, ti wọn ko ba lọwọ si, ẹni ki wọn bọ sita," o sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ.
Siwaju sii lo tun fi kun ọrọ rẹ pe, "Teeyan ba fẹsun ti kii ṣe temi kan mi, maa bọ sita lati fohun silẹ, maa si ṣe fọnran lati tako ẹsun ti wọn ba fi kan mi.
"Ẹ sọ fun Tope Alabi ko bọ sita. Tope Alabi a ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, Tope Alabi a fi ọmọ ologo ṣetutu. Ko ṣẹṣẹ maa ṣee, o ti n ṣe tipẹ ki Ọlọrun to wa tu aṣiri ẹ sita lasiko yii.
"Awọn to n fi ọmọ ologo ṣetutu lo pa Bayonile ni, wọn sọ fun wọn ninu ẹgbẹ wọn pe ki wọn lọ mu ọmọ olokiki wa, lati fi ṣe irapada okiki. Nnkan ti Tope Alabi ṣe niyẹn.
"Bi Aduke Gold ṣe ku niyẹn, bi Omije Ojumi ṣe ku niyẹn, aimọye wọn bẹẹ ti wọn ti ṣanku. Ọlọrun ko ba ọmọ ẹda ṣe adehun da majẹmu iku aitọjọ. Majẹmu ẹmi gigun ni Ọlọrun ba awa ẹda da."




























